BBC News, Yorùbá - Ìròyìn
Ìròyìn tó ṣe kókó
Ogun Abẹ́lé Sudan: Akọ̀ròyìn tó há sínú ogun fún ọdún mẹ́ta sọ ohun tójú rẹ̀ rí
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ Sudan ni wọ́n ti fọ́nká káàkiri báyìí, àwọn míì ti sá lọ sí orílẹ̀ èdè mìíràn lójúnà àti bọ́ lọ́wọ́ ìpèníjà tó ń bá gbogbo ayé fínra.
Àlàyé rèé lórí ìdí tí ìjọba ṣe yọ ẹ̀sùn fifi owó ṣèrànwọ́ fún ìgbẹ́sùnmọ̀mí kúrò nínú ẹjọ́ ti Malami ń jẹ́
Tẹ o ba gbagbe, Malami ati ọmọ rẹ; Abdul Aziz ni wọn jọ n jẹjọ to ni i ṣe pẹlu nini nnkan ija ogun lọwọ lọna aitọ, ati ti pe wọn n ran awọn agbesunmọmi lọwọ.
Kí ni Cute Abiola ṣe, tí omíjé fi ń dà lójú rẹ̀ àmọ́ tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń sọ̀rọ̀ si?
Iṣẹ abẹ ni iyawo Cute Abiola torukọ rẹ n jẹ Khudrah Mosunmola fi mọ, ko si too di pe wọn gbe e wọ yara iṣẹ abẹ naa ni oun ati ọkọ rẹ ti bẹrẹ fidio to n ṣafihan bi igbesẹ oyun naa ṣe n lọ han.
A gbàgbọ́ pé àlàáfíà yóò jọba ní Cameroon lẹ́yìn àbẹ̀wò Pope Leo XIV- Aráàlú
Awọn olori ẹsin ati araalu rẹpẹtẹ to ti n duro de Papa naa ni wọn fi tilu-tifọn ki I kaabọ.
Àlàyé rèé lórí ìdí tí ààrẹ Trump àti Pope Leo XIV ṣe ń tahùn síra wọn
Poopu sọ fawọn akọroyin nigba to n lọ si orilẹede Algeria wi pe oun ko ni ṣe arohun-bọhun pẹlu Trump, amọ, oun ko ni dakẹ lati maa sọrọ tako ogun.
Àbọ̀ ìwádìí BBC lórí ikú ìyàwó Wòlíì olùdásílẹ̀ ìjọ tó ń ṣe ọ̀pọ̀ èèyàn ní kàyééfì
Lẹyin ọdun mẹwaa ti Charmain ti ku, iwadii BBC fi kudiẹkudiẹ han ninu ọrọ ti Adusah, ọkọ rẹ̀ sọ.
Orin, Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́, Duration 1,01
Kò ṣeé má gbọ̀ọ́
"Bí Ishmail tí iná gbé ní Ilorin ṣe ń kàwé, ló ń ṣiṣẹ́ láti jẹ́ èèyàn láyé, owó díẹ̀ tó rí ló fi ra Kọ̀ǹpútà tó gbiná"
BBC News Yorùbá dé ilé Ishmail Olatunbosun ní Ilorin, ọkùnrin tó ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ìsìnrú ìlú tí iná ọba tó lágbára pa, àwọn ẹbí rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ìlàkàkà rẹ̀ láti jẹ́ èèyàn, kó tó kú láìpé ọjọ́.
Móríwú
BBC News Yorùbá ti wà lórí ìkànnì WhatsApp
Má jẹ́ kí etí rẹ ó di sí gbogbo ìròyìn ohun tó ń lọ ní Naijiria àti káàkiri àgbáyé. Mọ̀ nípa wọn lórí ìkànnì Whatsapp rẹ
Ìròyìn Àkàgbádùn
Kí ni alága àjọ INEC ṣe tí MURIC ṣe yarí pé lílọ ni yóò lọ àmọ́ táwọn ọ̀dọ́ ìlú rẹ̀ ṣèwọ́de àtìlẹ́yìn fún un?
MURIC sọ ninu atẹjade to fi sita wi pe ''inu wa ko dun pẹlu ijọba lori bi wọn ṣe dakẹ nipa ohun ti ajọ awọn musulumi beere wi pe ki wọn yọ alaga INEC nipo.
Dárúkọ pẹ̀lú ẹ̀rí tó dájú àwọn tó fi rìbá lọ̀ ọ́ láti gbé ìgbésẹ̀ ìyọnípọ̀ Makinde bíbẹ́ẹ̀kọ́... - Olórí ilé aṣòfin àná
Èyí ló ń wáyé lẹ́yìn tí Ogundoyin fẹ̀sùn pé àwọn kan fi owó tabua àti àtìlẹyìn ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC lọ òun tí òun bá ṣe ìlànà yíyọ Seyi Makinde.
Lẹ́yìn ìwọ́de tako ìjínigbé, Aiyedatiwa ṣàbẹ̀wò sáwọn agbègbè tí ààbò ti mẹ́hẹ, ó ní ajínigbé 100 tó ń ṣọṣẹ́ l‘Ondo ní ọwọ́ ti bà
Gomina sọ awọn ọrọ yii lasiko abẹwo ibanikẹdun to ṣe si Aafin Olumafon tilu Imafon, Oba Samuel Adegbehingbe Aliu lọjọ Isẹgun.
Àwọn ọmọ Iran kọminú lórí bóyá ogun Amẹ́ríkà lè tẹ̀síwájú tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́ lẹ́yìn tí ìpàdé àláfíà forí ṣánpọ́n
Ibaṣepọ ti ko dan mọran to wa laarin Iran ati Amẹrika tunbọ buru siwaju si lẹyin ti ipade alaafia laarin orilẹede mejeji to waye ni Pakistan lulẹ.
Amẹ́ríkà gbégi dínà Strait of Hormuz láti dí Iran lọ́wọ́ gbígbé epo gba ibẹ̀, China figbe ta pé ewu ń bẹ̀, bí owó epo ṣe wọ́n sí ní àgbáyé
Ijọba ilẹ Iran daba wiwọgile ipese Uranium fun ọdun marun un lati fopin si ogun to lọ lọwọ naa.
'Òkú mẹ́rìndínlọ́gọ́ta ni mo kà láàárín ìlú, ọ̀pọ̀ ló fọ́nká sínú igbó'
Bí àdó ikú látọ̀dọ̀ àwọn ológun Nàíjíríà tún ṣe balẹ̀ sórí aráàlu ní ọjà kan tó wà láàrin ààlà ilẹ̀ ìpínlẹ̀ Borno àti Yobe, BBC News Yoruba se akojọpọ awọn akoko mẹfa ti baalu ologun ti seesi kọlu araalu.
Ìdí rèé tí Iyabo Obasanjo ṣe gba kámú bí gbogbo ẹgbẹ́ APC l‘Ogun ṣe fa Yayi kalẹ̀ bíi olùdíje gómìnà
Ọjọ Aje, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹrin ọdun 2026 ni Abiodun fa Yayi kalẹ, lasiko ipade awọn alẹnulọrọ ẹgbẹ APC nipinlẹ Ogun.
Ọkọ̀ tó kó àwọn agbábọ́ọ̀lù pàdé àwọn adigunjalè lọ́nà, wọ́n yìnbọn pa agbábọ́ọ̀lù kan
Ikọ agbabọọlu Berkum Chelsea ti Dominic wa lo ko awọn adigunjale lọna lọjọ Aiku ọsẹ yii.
Ìjọba gbẹ́sẹ̀ lé dúkìá afurasí mẹ́tàlá tó ń ṣagbátẹrù ìgbésùnmọ̀mí
Igbesẹ yii gẹgẹ bi ajọ SEC ṣe ṣalaye da lori ofin ọdun 2022 to tako igbesunmọmi eyi to sọ pe ijọba gbọdọ gbẹsẹ le owo, dukia ati nnkan ọrọ aje ẹnikẹni to ba n ṣagbatẹru fun igbesunmọmi lai sọ fun wọn tẹlẹ.
Àwọn ìdí rèé tí gómìnà kan fi le yọ ọba nípò lábẹ́ òfin
BBC News Yorùbá kàn sí onímọ̀ nípa òfin láti mọ̀ nípa ohun tó le ṣokùnfà kí ìjọba fi àṣẹ gba adé lórí ọba àti ìlẹ̀kẹ̀ lọ́rùn rẹ̀.
''Mi ò sọ pé àṣìṣe wà nínú òfin owó orí tuntun ilẹ̀ Nàìjíríà, wọ́n ṣì mí gbọ́ ni'' -Mínísítà ìpínlẹ̀ fún ètò ìṣúná
Ninu atẹjade ti 'Presidential Fiscal Policy and Tax Reforms' fi sita lọjọ Aiku ni minisita naa ti sọ pe iroyin to le ṣi araalu lọna ni wọn n gbe kiri.
Èèyàn bíi 400 rí ẹ̀wọ̀n he lórí ìbáṣepọ̀ wọn pẹ̀lú agbésùnmọ̀mí ní Naijiria
Lara awọn idajọ ti awọn afurasi naa gba ni idajọ ẹwọn ọdun marun un si ẹwọn gbere fun ibaṣepọ wọn pẹlu ẹgbẹ agbesunmọmi Boko Haram ati ẹgbẹ Islamic State West Africa Province (Iswap) to yapa kuro ni Boko Haram.
Ìròyìn Pàtàkì
Kọ́milẹ́kọ̀ọ́
Ẹ tẹ̀lé wa lórí ìkànnì ayélujára
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Wo kókó ohun márùn-ún tí Pope ń bọ̀ wá ṣe nílẹ̀ Áfíríkà lẹ́nu àbẹ̀wò ọlọ́jọ́ mẹ́wàá tó bẹ̀rẹ̀ lónìí
Àbẹ̀wò Pope Leo XIV sílẹ̀ Africa yìí ló máa jẹ́ ìrìnàjò rẹ̀ tó gùn jùlọ láti ìgbà tó ti di póòpù ìjọ Àgùdà.
Ìjọba yóò máa gba ìwé ìrìnnà lọ́wọ́ àwọn tó bá ní àwọn kì í ṣe ọmọ Naijiria mọ́
Atẹjade naa ṣalaye pe awọn eeyan ti Aarẹ ba ti gba pe awọn ki i ṣe ọmọ Naijiria mọ ni ọrọ yii kan.
Ààrẹ Omar Guelleh tún wọlé sáà kẹfà ní Djibouti, lẹ́yìn ọdún 27 tó ti wà nípò
Ọpọ awọn to yẹ ki wọn jọ dupo aarẹ naa ni ko ba wọn kopa, awijare wọn si ni pe ko si akoyawo ninu idibo orilẹede naa mọ.
Àwọn afurasí jàndùkú agbébọn ṣekúpa ìyá àti ọmọ l'Ondo
Iṣẹlẹ yii lo tun ti fa ibẹru bojo bayii ni agbegbe naa, bi awọn eniyan se n sa asala fun ẹmi wọn, ti wọn si n kọminu lori ipo ti ọrọ eto aabo wa ni Ipinlẹ Ondo.
Ìdílé oyè fún Gómìnà Adeleke ní gbèdéke ọjọ́ méje láti rọ Apetumodu tó ń ṣẹ̀wọ̀n l'Ámẹ́ríkà lóyè
Ile ẹjọ kan lorilẹede Amẹrika lo dajọ ẹwọn fun Ọba Apetumodu ti ilu Ipetumodu ti wọn ni o jẹbi ẹsun lilu jibiti pẹlu eto ẹyawo COVID-19 ti wọn gbe kalẹ lati ṣe iranwọ fun awọn okoowo kekeke to fara kaasa lasiko ajakalẹ arun naa.
Wo bí o ṣe lè wo, tàbí ṣe àtẹ̀jáde ìwé atọ́nà pélébé fún ìdánwò Jamb UTME
Ajọ Jamb ni idanwonaa yoo ṣi waye laarin ọjọ kẹrindinlogun si ikarundinlọgbọn oṣu kẹrin ọdun 2025 ti wọn kede tẹlẹ.





































































